Play Open

ÌRÒYÌN

ALÁBOJÚTÓ ÌRÒYÌN L’ÉKÌTÌ ṢÈLÉRÍ ÀTÌLẸYÌN FÚN ILÉ-IṢẸ́ LÀÁKÀYÈ TÍ YÓÒ MÚ ÌDÀGBÀSÓKÈ DÉBÁ ÀWỌN OHUN ÈLÒ TÓ WÀ LÓJÚKÒ ÌBẸ̀WÒ

Alábojútó ẹ̀ka ìròyìn l’Ékìtì, Ọlọ́lá Táíwò Ọlátúnbọ̀sún, ti tẹnumọ́ ìmúratán ìjọba láti ṣe àtìlẹ́yìn fún’lé iṣẹ́ tó nlo làákàyè láti mú ìdàgbàsókè bá áwọn ojúkò àbẹ̀wò l’Ékìtì. Ọlọ́lá Ọlátúnbọ̀sún tẹnumọ́ ìpinnu Gómìnà Èkìtì, Ọ̀gbẹ́ni Bíọ́dún Oyèbánjí láti ríi dájú pé àwọn ojúkò àbẹ̀wò l’Ékìtì jẹ́ èyí tó n pa owó tabua sí àpò ìjọba Èkìtì, pé àwọn ilé-iṣẹ́ tó n.. Read more

ÌJỌBA ÀPAPỌ̀ YÓÒ MÚ OJÚṢE IṢẸ́ Ọ̀NÀ LỌ́KÚNKÚNDÙN – UMAHI LÓ ṢÈDÁNILÓJÚ NÁÀ FÚN GÓMÌNÀ OYÈBÁNJÍ

Mínísítà fúnṣẹ́ òde, Olùmọ̀ẹ̀rọ Dave Umahi ti gbóríyìn fún Gómìnà Èkìtì, Ọ̀gbẹ́ni Bíọ́dún Oyèbánjí fún ìfarajì rẹ̀ lórí ìpèsè àwọn ohun amáyérọrùn ní ìpínlẹ̀ yí tó sì nfi dáa lójú pé ìjọba àpapọ̀ yóò ṣe kóyákóyá sáwọn ojúṣe ọ̀nà tó n lọ lọ́wọ́lọ́wọ́ àtàwọn tíjọba àpapọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé fún kóngilá l’Ékìtì. Àkókò tí Umahi wá ṣe àbẹ̀wò sáwọn ọ̀nà l’Ékìtì.. Read more

KỌMÍṢỌ́NÀ FÚNLÉ IṢẸ́ ÌPÈSÈ NÍNÍ ÀLÙYỌ PÈ FÚN ÀTÌLẸ́YÌN ÀWỌN ỌBA LÓRÍ BÁNKÌ LẸ́SẸ̀ KÙKÚ

Lójúnà àti mú kó rọrùn fáwọn ìlú àti ṣàgọ́dabúlé l’Ékìtì láti máa rówó gbà lóòrèkóòrè, nìjọba ṣe fẹ́ gbé bánkì orí ẹ̀rọ ayélujára kéékèèkéé káàkiri àwọn ìlú àti sàgọ́dabúlé l’Ékìtì kalẹ̀ tí ìjọba sì n képe awon ọba láti fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ojúṣe tuntun náà láti mú kó kẹ́sẹ járí. Àkókò tí alábojútó ilé-iṣẹ́ tó n rísí ìpèsè ọrọ̀ àtiṣẹ́ l’Ékìtì,.. Read more

ÌJỌBA ÉKÌTÌ RA ỌGBỌ̀N ỌKỌ̀ LÁTỌ̀DỌ̀ ÀWỌN OLÙTAJÀ ỌKỌ̀ LẸ́SẸ̀ KÙKÚ LÁTI KOJÚU ÈTÒ ÀBÒ LÉKÌTÌ

Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkìtì,Ọ̀gbẹ́ni Oyèbánjí ti ra ọgbọ̀n ọkọ̀ látọ̀dọ̀ àwọn oníṣòwò ọkọ̀ lẹ́sẹ̀kùkú láti gbógun ti àìsetò àbò tó gbòde kan lákókò yìí,tígbésẹ̀ ọ̀hún yóò ró àwọn Amọ̀tẹ́kùn lágbára kíwọ́n leè gbógun ti àwọn ajínigbé ní ìpínlẹ̀ yí.Oyèbánjí sọ pé,ríra àwọn ọkọ̀ wọ̀nyí látọ̀dọ̀ Oníṣòwò l’Ekìtì fi ìdíi rẹ̀ múlẹ̀ pé ìsèjọba rẹ̀ nṣe àmúsẹ òfin àmúgbòòrò ọrọ̀ ajé tiwantiwa.. Read more

ALÁGA ILÉ-IṢẸ́ SUBEB GBÓRÍYÌN FÚN ÀWỌN ÒṢÌṢẸ́ FÚN IṢẸ́ TAKUNTAKUN TÍ WỌ́N ṢE LÓRÍ ÈTÒ Ẹ̀KỌ́ ALÁKỌ́BẸ̀RẸ̀ L’ÉKÌTÌ

Alága ilé-iṣẹ́ tó n rísí ètò ẹ̀kọ́ alákọ́bẹ̀rẹ̀ l’Ékìtì, Ọ̀mọ̀wé Fẹ́mi Akínwùnmí ti gbóríyìn fún àwọn òṣìṣẹ̀ ilé-iṣẹ́ náà fún akitiyan wọn lẹ́nu iṣẹ́, eyí tí ó mú ipele ẹ̀kọ́ alákọ́bẹ̀rẹ̀ tayọ láti bíi ọdún kan sẹ́yìn l’Ékìtì. Nígbà tó n sọ̀rọ̀ níbi àgbéyẹ̀wò iṣẹ́ àwọn ẹ̀ka-ò-jẹ̀ka ilé-iṣẹ́ náà nílù Adó, Ọ̀mọ̀wé Akínwùnmí sọ pé akitiyan àwọn òṣìṣẹ̀ náà ni.. Read more