Play Open

ALÁBOJÚTÓ ÌRÒYÌN L’ÉKÌTÌ ṢÈLÉRÍ ÀTÌLẸYÌN FÚN ILÉ-IṢẸ́ LÀÁKÀYÈ TÍ YÓÒ MÚ ÌDÀGBÀSÓKÈ DÉBÁ ÀWỌN OHUN ÈLÒ TÓ WÀ LÓJÚKÒ ÌBẸ̀WÒ

Alábojútó ẹ̀ka ìròyìn l’Ékìtì, Ọlọ́lá Táíwò Ọlátúnbọ̀sún, ti tẹnumọ́ ìmúratán ìjọba láti ṣe àtìlẹ́yìn fún’lé iṣẹ́ tó nlo làákàyè láti mú ìdàgbàsókè bá áwọn ojúkò àbẹ̀wò l’Ékìtì.

Ọlọ́lá Ọlátúnbọ̀sún tẹnumọ́ ìpinnu Gómìnà Èkìtì, Ọ̀gbẹ́ni Bíọ́dún Oyèbánjí láti ríi dájú pé àwọn ojúkò àbẹ̀wò l’Ékìtì jẹ́ èyí tó n pa owó tabua sí àpò ìjọba Èkìtì, pé àwọn ilé-iṣẹ́ tó n fi iṣẹ́ ọwọ́ ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan han, àṣà àtàwọn ojúkò àbẹ̀wò máa njẹ́ igi lẹ́yìn ọgbà fáwọn ìpínlẹ̀ láti máa powó gọbọi sápò ìjọba.

Yàtọ̀ sí èyí, Kọmíṣọ́nà fétò ìròyìn ọ̀hún sọ pé ìjọba Èkìtì ti pinnu àti fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ilé-iṣẹ́ aládáni mú ìdàgbàsókè débá àwọn ojúkò àbẹ̀wò wọ̀nyí láti leè pèsè iṣẹ́ fáwọn ènìyàn, kí òṣì àtàre sì dohun ìgbàgbé lẹ́sẹ̀kùkú l’Ékìtì.

Níbáyìí, ìpínlẹ̀ Èkìtì ti gbàlejó lórí ojúṣe ìgbélárugẹ orí òkè safari ẹlẹ́ẹ̀kẹfà rẹ̀.

Lára àwọn ojúṣe ọdún Àjínde tó kọjá yíí nìjọba Èkìtì ti gbàlejò onírúurú àwọn ènìyàn lorí ìsọdọ̀tun àfihàn òkè fíofío safari l’Ékìtì – ọjọ́ kíní, oṣù kẹ́rin yí lojúṣe náà wáyé.

Olùdarí àgbà fúnlé iṣẹ́ tó n rísí ìdàgbàsókè àwọn ojúkò àbẹ̀wò l’Ékìtì, Ọ̀gbẹ́ni Wálé Òjó-Lánre sọ pé ojúṣe bíi ayẹyẹ ẹkáàbọ̀, eré ìdárayá apanilẹ́rín àti mímú orí òkè Abanijọrin tó wà ní ìlú Ìyìn-Èkìtì gùn, èyí tó ga tó ẹsẹ̀ bàtà ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún (900metres) ló wáyé.

Òjó-Lánre sọ pé àwọn èrèdí fún ojúṣe wọ̀nyí ni láti ṣe àmúlò àwọn ohun àmúṣọrọ̀ t’Ékìtì ní láti mú àyípadà olóore àtìdàgbàsókè débá ìpínlẹ̀ yí, tí yóò túnṣe móríyá fáwọn àlejò láti wá máa dálé iṣẹ́ sílẹ̀ l’Ékìtì, ó sọ ìmúratán arábìnrin Lọlá Adé-John láti lọ́wọ́sí ojúṣe náà àti ṣíṣe àbẹ̀wò sójúkò ibi tómi gbígbóná àti tútù ti pàdé nilù Ikọgòsì-Èkìtì.

Olùdarí àwọn ibi àbẹ̀wò l’Ékìtì náà sọ pé, ìpínlẹ̀ yí yóò tún jànfàní ìlọ́wọ́sí ìjọba àpapọ̀, ẹ̀ka tó n bójútó àwọn ojúkò àbẹ̀wò àtèyì tó n rísí ìtọ́jú lórí ìdánilẹ́kọ́ lórí ọ̀kan-ò-jọ̀kan báa ṣe leè lo àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé láti mú ìsọdọ̀tun àyíká wá tí yóò ran áwọn ìlú tó wà lágbègbè ibi táwọn ojúkò àbẹ̀wò bá kalẹ̀ sí.

Ó ní àgbékalẹ̀ yí yóò ṣe àfikún sí àwọn ìrírí àwọn olùbẹ̀wò, àyípadà ìlú àtìdàgbàsókè ọrọ̀ ajé l’Ékìtì.

Posted in ÌRÒYÌN
Previous
All posts
Next

Write a comment